KINI IWE MIMỌ WI?

KINI IWE MIMỌ WI?

FOR YOU TO KNOW WHAT BIBLE SAYING

05/12/2023

ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ, EYI NI LATI FITO GBOGBO ÀWA ỌMỌ ỌLỌRUN LETI PE, ẸKỌ LATI MỌ ÀṢÍRÍ AWỌN ÈMI ÒKÙNKÙN TO DARA PỌ MỌ ÌHÌNRERE , TO TAN ỌPỌ ÈNÌYÀN BI PE MÍMỌ NI OHÙN, ẸKỌ NIPA TITU ASIRI ÒKÙNKÙN L'ARIN IMỌLẸ ÌHÌNRERE YIO BẸRẸ LORI FACEBOOK LIFE VIDEO
ẸKỌ YI, YIO ṢE PÚPỌ AFANI FUN ỌPỌ ÀWA CHRSTEN LATI NI OYE IRỌ ATI AREKEREKE SATANI, KALE BỌ LỌWỌ RẸ, LATI ẸNU EVANG OLUWAFEMI AYANFẸ JÉSÙ, NI 10/12/2023, NI DEDE AGOGO MÁRÙN IRỌLẸ, FÚN IBERE ATI ỌRỌ IYÀNJÚ 07031466235 ỌLỌRUN YIO SỌ WÀ JU ÌGBÀ NA LỌ NÍ ORUKO JESU OLÙGBÀLÀ ÀMÍN

30/11/2023

KINI IWE MIMỌ WI? FOR YOU TO KNOW WHAT BIBLE SAYING

29/11/2023

Kristiani ti o ba fe de ile ogo gbogbo
sora fun nkan meje yi.

1. Asise ti ko ni latunse.
2. Ese ti o ma da ti o ko ni le jewo.
3. Ohun ti o ma baje ti o ko ni le tunse.
4. Ija ti o ma ja tabi da sile ti ko ni le pari
5. Oro ti o ma so ni ikoko, ti o ko ni le so ni gbangba.
6. Nkan ti o se fun eniyan, ti o ko fe ki won se fun o.
7. Egbe ti o ko le so ni gbangba pe o wa lara won - 1Kor.15:33.

29/11/2023

AKOORI ORO IYANJU MI FUN WA LONI NI EYI

IBUDO OGUN TI OGA JÙLỌ, NI ỌKAN ENIYAN

Papa jùlọ awa Christen, A le borí tabi padanu ìṣẹgun yi ninu ọkan,
Awọn ọta mẹta timotimo kan hùwa bi mẹtalọkan, A ko le yáa wọn, awọn ọta wọnyi fi ìmọ wọn s'ọkan papa lori irin ajo Christen, awon ota wọnyi ni Èṣù, Ayé, Ẹran ara, ayé dúró gegebi ibodo Ogun na, ẹran ara dúró gegebi ohun elo ìjà ọta si Christen, Èṣù dúró gegebi jagun jagun, awọn mẹtẹta wọnyi, inu ọkan eniyan ni wọn fi ṣe ibùdó wọn, nipasẹ arekereke ni iṣẹ iransẹ wọn ninu ọkan, ọta mẹta ti ifarahan rẹ jẹ ẹyọkan yi kifi ìgbà kankan simi, ojúṣe ifojusun rẹ gan ni Ole jíjà, ohun kan losi wa lati ji lọwọ Christen, kini ohun ti ọta yi wa lati ji lọwọ awa Christen? (a) owo, (b) ola, (c) ogo aye wa, (d) igbala ọkan waa, ninu ikan merin yi ikan loje ọta yi logun ju, ikan soso na ni igbala ọkan wa, ojojumọ lo ṣíṣe láti ji gbe ninu ayé wa, nitori o mọ pé oje ohun tó ṣe iyebiye fún Christen, amo Ose mi l'anu pe awa Christen a nani ikan yi rara, oti fún ọta yi lafani lati sọ ayé ọpọ Christen di korofo, oti jaa wọn lolè ikan pataki, amo wọn ṣebi awọn síwá laye nigbati won ti ku, bawo ni Christen sele borí ọta yi?
Ọnà kan ṣoṣo tí apin sí ipa meje ni asiri yi wa, kini asiri agbara ọta yi? Epade mi ninu apa keji ọrọ iyanju na, ore ọfẹ Jesu kristi Olugbala kodi gbogbo wa mu t**i lailai ni orúkọ Jésù ÀMIN

28/11/2023

(ẸKỌ) AMUNIKOSE ATINISISE LOJU ỌNA IYE,

ìjọ jẹ ẹgbẹ meji, onigbagbọ tabi alaigbagbọ, ọlọgbọn ati alaigbon, ẹni mímọ àti aláìmọ, ni gbogbo ijọ laye, ẹbi, ara ati ojúlùmò, awọn enia meji lowa, awọn enia mimọ, ati awọn alakoba enia, awọn alakoba yi jẹ aṣòdì nitori ti wọn jẹ ẹni búburú, wọn k'isẹ ero orun, ṣugbọn wọn jẹ alakoba awọn arinrin ajo ilu orun, alakoba ki ko ba igi, enia ni wọn má ko ba, awọn alakoba wa ninu ijọ, ninu ẹbi, ati ni àdúgbò, a njo wole a njo jade ni, awọn alakoba yi larin ẹgbẹ akọrin, wọn pọ ninu oṣiṣẹ Ọlọrun, ko le sẹsẹ ki awọn alakoba yi ma wa, wọn a dàbí epo larin alik**a, wọn jẹ ọta òdodo, ọta ìwà mímọ, ṣọra ki wọn ma ba koba ọ, iwọ yíò si di apadaseyin sinu Egbe, ninu iwe (NUMERI 11:5,6-7) NI ijade awọn ọmọ Israẹli, awọn àdàlú tẹle wọn, nibiti a ba ti rí àwọn Olusin tooto, àdàlù na yíò wá ni ibẹ, awọn àdàlú ènìyàn yi ni awọn ọmọ egypti, ọkan wọn ati iwa wọn ti egypti ni, ko ṣe eku, ko ṣe ẹyẹ ni wọn, kosi iwasu ati ẹkọ tí wọn kò mọ, ṣugbọn alatako òtítọ niwọn, ki pe su wọn, wọn mọ ibẹrẹ ìjọ, gbogbo oriki Olúwa bẹ lẹnu won, ọrọ wọn dabi ORPA, wọn jẹ ejo larin ijọ, alaisorote ni wọn, bi o bá yẹ wọn, wọn a dúró, bi ìṣòro bade wọn o sa pada, (owe 21:10) alaigbon ni wọn, ajegbodo niwọn, gbogbo ero won mada le ara ni igba gbogbo, iwọ ero orun, mọ wọn kò yẹra fún wọn, satani lo ṣe ètò wọn ninu ijọ, ki ọpọ le sọ ile ologo ni, é wò àkóbá ti àrònì jẹ fún àwon ọmọ Israẹli, igbákejì lo jẹ fún Mósè, on na lo ko ba Mósè, Dawon mọ, ma ba wọn ṣe ọrẹ, yẹra fún arákùnrin tó rin segesege (Rómù 16:17) awọn apẹrẹ alakoba ninu ayé, ẹbùn le koba enia, ìrònú le koba enia, ìwà le koba enia, enia le koba enia, ọmọ le koba òbí, òbí le koba ọmọ, olùṣọ àgùntàn le koba ọmọ ijọ, ọmọ ijọ le kaba olùṣọ àgùntàn, báwo la ṣe lè bọ lọwọ AMUNIKOSE ATINISISE LOJU ỌNA IYE Ipade di apa keji, Evang Oluwafemi ayanfẹ Jésù ni orúkọ mí, t**i di igba naa, aoni di idakuda ninu Jésù olore ọfẹ ÀMÍN

10/10/2023

AIFURA, MU, AJAGUN ṢUBU, LOJU ÌJÀ

matthew 13, 25 sugbon nigbati enia sun, ọta rẹ̀ wà, ofun eèpo sinu alik**a, osi ba tirẹ lọ,
Hummḿḿ, emaje koya wa lenu pe pupo Christen loni, loti sun, èṣù ti fọn eèpo sinu alik**a wọn, sibẹ wọn o fura rara pe awọn ti sun, ninu awọn ẹkọ ti ati ko wa seyin, ati jẹ koye wa pé jagunjagun ni Christen je láyé, èṣù ni ọta ti Christen nba ja ogun lojojumọ, èṣù kì simi, èṣù kì rẹwẹsi, èṣù kì Gba kámú boro, èṣù kì sun, ojojumọ ati igba gbogbo ni èṣù fi ṣíṣe iransẹ rẹ laisimi ati lai sare, amo awa Christen lama rẹwẹsi, ninu iṣẹ iransẹ wa ninu adura gbigba ati di ọ lẹ, kilofa púpọ wa ni àní afi ayé wà fún Jésù, amo njẹ nigbati afi ayé wa fún Jésù nje afi aye ati àkókò silẹ fún pẹlu, haaaaaa, anife akoko wa ju Jesu lọ, njẹ bẹni irin àjò awọn aposteli seri ninu Bibeli wa, ninu irin àjò Jésù laye ọjọ wo lo simi, amo awa ofi akoko silẹ fún eyi rara, awa pe ara wa ni ọmọ leyin Jésù, haaaaaaa Iro nla, abajo ninu matthew 19-16-25, ọmọkùnrin ọlọrọ to tọ Jésù wà, oni olùkọ ní rere, kini ohun ti mole ṣe ki emi lè jogún ìyè àìnípẹkun, Jésù wifun pe pa ofin mọ́, ọmọkùnrin yi wa sọ fún Jésù pé lati kékeré ohun ni ohun tipa ofin mọ́, Jésù wipe, ti oba fẹ latidi pipe, lọ tá gbogbo ohun ini rẹ kosifi owo rẹ fún àwọn talakà, ko ṣẹṣẹ wa ma tọ mi leyin, bíbélì wipe inu ọmọkùnrin na bajẹ, haaaaa, kilofa? Akọkọ oni ọrọ owo to pọ, ekeji kole fi aye ati àkókò silẹ lati ma tọ Jésù leyin, amo ofe ọrọ òfin dada, bẹẹ p**a ofin mọ ko sọ enia di pipe níwájú Jésù, eyin eniyan mi ninu Oluwa, njẹ awa papa nfi akoko wa silẹ fún Jésù bí? Hummḿḿ laiṣe eyi, eniyan kotidi pipe níwájú Ọlọrun lati jogun iyee àìnípẹkun na, ẹjẹ ki aji pada ninu orun wa, ninu irẹwẹsi wa, èṣù ofi iṣẹ iransẹ rẹ jafara rara kofi igba kankan sinmi, fifi ayee ati àkókò silẹ fún Jésù Ose pataki fún Jésù ju ohun gbogbo lọ, ni orúkọ Jésù aoni jẹbi ni ìkẹyìn ọjọ ÀMIN

10/10/2023

Moki gbogbo awa ọmọ Ọlọrun lapapọ ninu iyara yi ni oruko jesu, ile ologo konidi ewọ fún gbogbo wa ní oruko jesu, laipẹ ao gbe ẹkọ yi yẹwo, kini Bibeli sọ nípa ọkàn enia, ọkan melo ni enia ni, agbara melo l'ose oludari ọkan enia, báwo ni enia ṣe lè yanda ọkan fún agbara toba wù?

10/10/2023

ÌWÀ BUBURU MẸSAN, TI OTAKO ESO EMI MẸSAN NINU AYE ENIYAN, PAPA AWỌN TI ỌLỌRUN BA FẸ

lakọkọ, awọn wo ni awọn ti Ọlọrun fẹ, ni otitọ gbogbo eniyan ni Ọlọrun fẹ, amo kise gbogbo eniyan lofe Ọlọrun, awọn to fẹ Ọlọrun ni awọn t**a ọrọ Ọlọrun mọ, awọn ti wọn tẹ lé àṣẹ rẹ, iru awọn wọn yi ni Ọlọrun fẹràn jù, amo iru wọn ni èṣù ma dọdẹ lati jà lo lè, (John 10:10) ole ikan to fẹ jà wọn ni ìgbàlà ọkan wọn, ninu bibeli ari bi Ọlọrun ṣe fẹràn sọlu púpọ l'arin awọn ọmọ Israẹli, Ọlọrun pan sọlu le púpọ o fẹràn rẹ gán, nipa bẹ, sọlu ṣubu laifura, ninu ayé sọlu ati ninu irin ajo rẹ, ni ati mamu ìwà mẹsan to tako eso emi mẹsan ti Ọlọrun fẹ ninu ayé eniyan, loni a ma mu ẹnu ba marin ninu iwa yi, iwa yi ni sọlu hu todi eni itanu lọdọ Ọlọrun, k'isẹ oun na bikose èṣù, èṣù ofi igba kankan simi lati da arin ayanfẹ Ọlọrun ati Ọlọrun ru, amo púpọ ayanfẹ loti ṣubu nitori ìsimi wọn, iwa akọkọ ti èṣù lo lati wọ inú sọlu ni iwa igberaga, (1 samuel 15:17, ema gbàgbé pé igberaga losiwaju ìparun (owe 16:18, lẹyìn èyí, iwa aigboran (1 samuel 15:19,) ema gbagbe pe ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ, gẹgẹbi ọrọ samuel sí sọlu, (1 samuel 15:22)
Iwa ìkẹta ní ìdá ara ẹni laré, sọlu ofi igba kankan ni ìdálẹbi ọkan ri, omafi igba gbogbo da ara rẹ ni are ni, ìwà ìkẹrin ibinu wọ inú ayé sọlu, (1 samuel 18:8) bẹ bíbélì wipe binu máṣe ṣẹ, (Efesu 4:26) amo sọlu binu osi tun ṣe,
Iwa ikarun ni oju kòkòrò, (1samuel 18:7-8) ema jẹ ká gbàgbé pé iṣẹ ẹran ara ní iwa oju kọkọrọ yi, (kilode 3:5) marun ni eyi nínú iwa búburú tó wọ inú sọlu wa, ti ofi di ẹni itanu lọdọ Ọlọrun, eyin ará mi ninu Oluwa njẹ iwọ na otifi àyè silẹ fún èṣù lati gbà ọ kan lára àwọn iwa yi wole sinu ayé rẹ? ma gbagbe awọn iwa yi loba ayé sọlu jẹ patapata, òṣì ku iwa rẹ mẹrin ti a mamu ẹnu ba, lẹyìn awọn iwa mẹsan yi, ni èṣù ṣẹṣẹ pa sọlu rún patapata, síwájú kí èṣù tó pa run, aye ironu piwada sí silẹ fún sọlu, amo sọlu kọ lati ronupiwada, iwọ olukawe mi, jọwọ aye ironupiwada rẹ re, tetee kọ àwọn ìwà yi silẹ loni ki ayé rẹ m'aba dabi ayé sọlu, ni orúkọ Jésù O

23/05/2023

KINI ANPE NI AGBELEBU?

ORÚKỌ ORÍṢIRÍṢI NI AWA ÈNÌYÀN FUN AGBELEBU

IṢẸ KINI AGBELEBU NṢE NINU IRIN AJO CHRISTEN, TI JESU FINI KA GBE KASI MATO OHUN LẸYÌN LUKU 9 VS 23
NJẸ ORÚKỌ TI AWA ÈNÌYÀN PE AGBELEBU ṢE OPAPO MO ỌKAN JESU

KIWANI EREDI TI AFI GBỌDỌ GBE AGBELEBU NÍNÚ IRIN AJO CHRISTEN

Nitori púpọ enia loma pe ìṣòro wọn ni agbelebu, ati iriri wọn, ati ilakoja wọn pe agbelebu awọn ni, nje beni ọrọ yi ri? Nje o ba ọkan Jésù mu fún ọrọ luku 9:23?
Lákọkọ́ e jẹki gbogbo wa koko mo pe, igi agbelebu jẹ igi ìdájọ awọn ọdaràn ni ilẹ àwọn júù, lori igi agbelebu ni awọn júù tí ṣe idajọ awọn ọdaràn ilu wọn, bi awa papa timo pe ẹran ara jẹ ọdaràn amuni dẹṣẹ, nítorí gbogbo iwa ẹran ara jẹ iwa ese ọdaràn sí Ọlọrun, GALÁTÍÀ 5:19-21, idi niyi ti christen se gbọdọ gbé agbelebu ni ọjọ gbogbo, nitori nibe ni ao tima ṣe idajọ ẹran ara wa nigba gbogbo, nitori lori agbelebu ni irin ajo Emi ti bẹrẹ, laigbe agbelebu yi ako le sẹgun ẹran ara asunida ese, kilose 3:5 ni k**a pa eya ara wa ti bẹ ni Aye run, Lori agbelebu lati le pa run,
Nitori idi eyi ni Jésù fini àní lati gbe agbelebu wa lojojumọ, kabale mafi ṣe idajọ ẹran ara wa nigba gbogbo, laipẹ a má wọnú ẹkọ yi dada, kalemo pàtàkì ohun ti agbelebu jẹ, ati iṣẹ tó ṣe nínú ìrìn àjò ọmọ lẹyìn Jésù, ao tẹsiwaju nipa rẹ ni ọlá ni oruko jesu, Ọlọrun yíò wá pẹlu gbogbo wa, emi ẹran ara koni mu wa subu loju ọna ìyè àìnípẹkun amin

20/05/2023

(APA KÍNI) ÀṢÍRÍ IṢẸ IRANSẸ SATANI

AWỌN WO NI SATANI LÉPA NINU IṢẸ IRANSẸ RẸ?

AWỌN WO NI ONI AGBARA LÁTI SẸGUN SATANI?

Lákọkọ́ moki gbogbo awa ọmọ Ọlọrun lapapọ ninu iyara ijile ẹkọ ninu Bibeli,

Iwe ìfihàn 12:7-17 muwa mọ diẹ nipa
Ifojusu èṣù láyè, satani ni awọn irinṣẹ merin kan, o ma lo awọn irinṣẹ yi lati
fi jere ọkan fún ara rẹ, kini oruko awọn irinṣẹ na? (1) ọgbọn (2) ẹtan (3) ète (4) arekereke, k'ise gbogbo eniyan ni ofi oju sí lára lati lo awọn irinṣẹ yi fún, awọn ti satani ko irinṣẹ yi wa bá ní awọn to ba jẹ wọ Jésù ni oluwa ati olugbala, kete ti satani bati ri enia pe o gba Jésù, ní jọ na ni oti bẹrẹ iṣẹ iransẹ rẹ lori ẹni náà, ọgbọn satani ni lati fi oriṣiriṣi ìdánwò ìṣòro kàn iru ẹni bẹẹ, ipọnju nla nla kan iru ẹni bẹẹ, lati le mú irú ẹni bẹẹ pada sẹyìn, awọn ilakoja ọgbọn satani yi, ni púpọ enia pe ni agbelebu lóni, laimo pe k'ise oun ni agbelebu, nigbati èṣù bari pe enia na kò lati pada sẹyìn nipa ọgbọn òun, yíò padà sí irinṣẹ Kejì t'ise ẹtan, ninu ẹtan rẹ oti mu kí ọpọ iransẹ Ọlọrun ṣubu, síbẹ wọn mọ pé awọn ti ṣubu sinu ẹtan satani, ẹtan yi ni satani lo fún Jésù olùgbàlà wa ninu Mattew 4:2-11, tobari pe enia kò lati ṣubu sinu ẹtan yi, yíò mú ète tí ṣe irinṣẹ kẹta, ète rẹ ni lati mu ki gbogbo eniyan kòrira eniyan ni ibi gbogbo, inunibini awọn enia yíò dìde sí irú ẹni bẹẹ, púpọ iṣẹ iransẹ satani yi ni an pe ni agbelebu lóni, iṣẹ iransẹ satani ni k'ise agbelebu, ti enia ba ko lati lù pàkúté ọgbọn, ẹtan,ete, satani yi, yíò mú ikan toku ninu irinṣẹ rẹ lati bá fi rìn rìn àjò ayé rẹ, irinṣẹ merin ni arekereke, ninu rẹ ni ọpọlọpọ ibapade loju ọna Emi wa lati ọwọ satani, arekereke rẹ lemu ayọ àti idunnu wa fún ènìyàn, Lai mope pàkúté ni, arekereke rẹ lemu wàhálà ipọnju idamu ba eniyan lati gbe ṣubu, awọn ti wọn ba bọ ninu pàkúté mererin yi, ni afi agbara fún lati di ẹni ìgbàlà, ka tó lè bọ lọwọ gbogbo awọn irinṣẹ yi, àní lati gbe ìpinu wa t'ise agbelebu, lati má kan gbogbo iṣẹ àwọn irinṣẹ yi mọ nígbà gbogbo, agbelebu ni agbara wà.

Want your public figure to be the top-listed Public Figure in Abeokuta?
Click here to claim your Sponsored Listing.

Category

Telephone

Website

Address

Asero
Abeokuta
Other Musicians/Bands in Abeokuta (show all)
ANOBI FUJI FANS CLUB ANOBI FUJI FANS CLUB
Oja Odan Yewa North Local Government
Abeokuta

Deejay Whizzy music entertainment world Deejay Whizzy music entertainment world
No 14 Adeyemo Str Obantoko Abeokuta
Abeokuta

Shubsboi1 music Shubsboi1 music
Abeokuta

Musician, songwriter �

Oladehinde Timileyin Oladehinde Timileyin
5, Dairo Str Idi Aba Abeokuta
Abeokuta, 110222

Ara Gospel band

Afibogun special komedy fans Afibogun special komedy fans
Ilugun Itoko
Abeokuta

This is L. B. M comedy group which is formed by broda shakky for birthday advert and others please c

Dç øluwå daniel Dç øluwå daniel
Isale Igbehin
Abeokuta, 108

We sing song

DidYou Know? DidYou Know?
Abeokuta

Eniolorun opa page Eniolorun opa page
Old Grammar School, IGBEIN Abeokuta
Abeokuta

Music producer,presenter at sweet 107.1fm&the CEO/DIRECTOR of ALL POSSIBLITIES MEDIA CONCEPT

De YOUNG Jentle Jay De YOUNG Jentle Jay
Abeokuta

De YOUNG Jentle Jay pages is making me feel better now than ever before

Irawonla Irawonla
Obantoko
Abeokuta

Songwriter||singer||recording&performing artist..for bookings☎️+234 7046984202📧olakunlegafar64@gmail

Òlüwàsèyí Òlüwàsèyí
Owode Egba
Abeokuta, OLUWASEYI

Believe in God

Ally mate official Ally mate official
F. H. E Elega
Abeokuta, 039

Musician/band