Kíláàsì Yorùbá
Ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa èdè, àṣà, ı̀ṣe, iṣẹ́ ati ẹ̀sìn Yorùbá fun gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀, Sẹ́kọ́ńdírì àti ẹ̀kọ́ àgbà
Alihamdulillah, "Akodan (Poem 📖Book)" is finally published on yorubabookshop.com Brother's, Sister's, Uncle's, Auntie's, Friends, Family and Fans, Now is the time for you to show your support, love, care towards me and Yorùbá Culture, kindly click on the link above 👆 and below 👇 yorubabookshop.com to subscribe and read "AKODAN POEMS" and other Yorùbá Literary work published by . Don't give me money, just subscribe on the site and download the book.
May Allah bless your pocket as you do.
Hard-Copy to be Published Soon
Ọdẹ tí yóó ṣọdẹ Ẹkùn kò ni múra ẹranko lásán tí bá ńlọ inú igbó ṣùgbọ́n ọdẹ tí yoo ṣọdẹ ẹranko lásán nínú igbó nlá, ó di dandan kó múra Ẹkùn lọ́wọ́ tori ko si ohun ti o le sele ninu igbo nla
Whoever wants to hunt a Tiger 🐯 might not prepare for small catch (animals) while entering the jungle but whoever wants to enter a jungle for small catch (animal) should prepare for a tiger 🐯 cos anything can happen in the jungle.
Kíláàsi Yorùbá ló ni: Ọ̀tọ̀ logun, ọ̀tọ̀ logún, ọ̀tọ̀ lòògùn, ọ̀tọ̀ lòógùn. Ẹni ti yóó lógún yóó làágùn bí ẹni ogun ńlé kiri kọ́rọ̀ rẹ̀ tò gún ṣùgbọ́n ẹni tí yóó gbójú lógún àbì jogún yóó sòògùn torí lógúnlógún ní wọn yóó máa gbógun tì í táyé yóó fi dogun fun, ló ṣe yẹ ká làágùn dénu egun kógun ayé máa bà kó ni lọ togúntogún.
A kú Ojúmọ́ ooo
Àmì ohùn nínú èdè Yorùbá ni a le pe ni ìgbóhùnsókè ìgbóhùnsódò nínú èdè Yorùbá. Mẹ́ta ni àmì ohùn tí a ni, awon náà ni
1. Àmì Ohùn Òkè ti a mọ si 'Mi' pẹ̀lú èyí ti (/) dúró fún
2. Àmì Ohùn Ìsàlẹ̀ tí a mọ̀ si 'DÒ' èyí ti (\) dúró fún
3. Àmì Ohùn Aarin tí a mọ̀ si 'RE' èyí tí (-) dúró fún
Àpẹẹrẹ:
Ọ̀rọ̀ òní sílébù kan: bá (meet), ba (hide), bà (to cover)
Ọ̀rọ̀ òní sílébù méjì: ọkọ́ (hoe), ọkọ (husband), ọ̀kọ̀ (spear), ọkọ̀ (lorry)
Ọ̀rọ̀ oní sílébù púpọ̀: àgbàdo (corn), elégéde (pumpkin), ìwádìí (Research)
Àkíyèsí:
★Orí fáwẹ́lì nìkan la maa n fi àmì si nínú èdè Yorùbá yala fáwẹ̀lì aranmupearanmupe tabi airanmupe
★Àmì ohùn oke ati ìsàlẹ̀ nìkan la maá n fi sórí ọ̀rọ̀
★Àmì ohùn jẹ àbùdá ara fáwẹ́lì kọ̀ọ̀kan èyí tó jẹ́ kí lílò rẹ pọn dandan
★Pàtàkì ni àwọn ami ohun yii ninu ede Yorùbá torí àwọn ná fi ìyàtọ̀ han láàrin oro méjì bi àpẹẹrẹ: igbá (Calabash), Ìgbà (Time), Igba (200 Hundred), Ìgbá (Fruits)
©️Mustapha Sherif
J.🅾️.R.🅰️
08147675392
Yorùbá Language (Spoken and Written): A Must for all Yorùbá Homes
I just laugh at our generation these days, many of us speak Yoruba to each other day in day out, but when you send a simple message in Yorùbá, we can't read it. We've been so blinded by western civilization and religion that we treat our language as trash, we forget the adage that says "Bonigba ba ti pe igba e, laraye o ba pe e". It's so funny how a Yorùbá family nowadays can hardly speak Yorùbá, our own language is now regarded as "VERNACULAR" even in our homes. Parents are ready to spend thousands on their wards just for them to be sound inEnglish but won't allow them to master their Mother Language which they can learn unconsciously. The most painful thing is majority of people are only good at the oral (speaking) of English, give them a pen and paper and see the blunder they commit even after spending a watering amount in learning it, many can't even write out the word they speak out correctly, I've seen many of them back at college and University.
We always say the Hausas are united unlike other tribes but we never pay attention to notice that their Language is part of what unite them. You walked into any office they occupy, they speak their language to each other and quickly help each other out but reverse is the case in ours, don't ever try to speak Yorùbá in an office occupy by a Yorùbá man even if he has a Big Trademark(TRIBALMARKS) on his cheeks unless you want your case or file to be delay. We see those that speak our Language uncivilized and unexposed even when he has travelled wide and far with the highest qualifications of education. You try engage people in Yorùbá language, it won't take long before you realize they don't have interest in whatever you are trying to pass across, no matter what just because of the Language you're using in conveying the message.
Language is part of what that makes a man, that's why when God created Adam he gave him a language and the messenger he send to each tribe use their language to preach to the people not otherwise. I don't see a reason why our Language can't be use to admonish ourselves, we shouldn't let religion blind us that you want to pray to your lord and you can't express yourself in Yorùbá (I'm not saying praying in other languages is wrong, especially in Obligatory Prayers) but when you are seeking (personal), it's better you pray using your mother tongue. Just like as Muslims and Christians, we strive hard to know the basics of our religion even though not all of us are masters or major (studied) in it, we should all try to know the rudiments of our language, culture and customs. You don't have to study Yoruba before you're able to express yourself fluently in it afterall you don't study Arabic or Tongue Speaking before you can use it to pray. You don't have to study Yoruba before you know your eulogy and that of your family. Just like you are not an Israelite or an Arab before you know the laws guiding your religion, you should try and know the taboos (EEWO) of your community, know the "does and don't".
"Omo ale eeyan na n ki loriki ile baba re, tori e ko ni wu" there is a connection between your spirits and your language, there is no way you will be praise or eulogize in your language that you won't be happy, our mothers make use of this in the olden days to sooth our fathers heart and make them grant their wish, our father use it to praise their wives whenever they make them happy. Nowadays, hardly will you see a house where they make use of such again, when they've tried to even do that to us, we tell them "we've disengage ourselves from such lineage and forefathers they are praising us with because we don't know the curse on them, so we won't want it to be us, we are very happy to announce to the world "we are now child of Christ and Muhammad" or that our Imam or Daddy G.O, we forget the two Prophets never disengage themselves from their family despite that many of them were idol worshippers before and even after they were prophets. *My Knight in shinning armour* the only line women of nowadays knows how to use in praising a man, please what happened to "omo ikoyii eso, omo olofa mojo,, omo oko irese, omo Ajana bogun bolu..." You think I will teach you? No, Listen to radio, read Yoruba novels, watch Yoruba films and learn. OH! let me ask you, have you ever praise your boyfriend/husband in English and he succumb. Oh😮 Someone said we now live a life of deceit and fake, so he might but it doesn't really convince him
Just like we master the quotes of Aristotle and others which only applies in few of our daily activities, why can't we quote Yoruba proverbs too that applies in everyday of life and activities. There are millions of Yorùbá proverbs and adage that suite every situation and topic of discussion. In as much as we can listen and sing Justin Biebier, Ed Sheeran, Celine Don songs and others, then what happened to Ayinla Omowura, Haruna Ishola, Olatunji Yussuf and Co? You can wear skirt and blouse with top, also trousers, shirts are your favorite but you feeling ashamed to tye wrapper, yeri, beti, sanyan, alaari, you don't have a single native wear, oh you think it makes you look awful, let be deceiving Ourselves. We copy Oyinbo white wedding and divorce 1-2 years after meanwhile Yorùbá Traditional wedding is there where they use local materials to pray for you in deep Yorùbá language but we see it as primitive acts. American films and fiction is our favorite, please what happened to Classic Yoruba movies. Unless we all stop this fake life and deceit, wake up and prioritise what's ours (our language, culture and customs) We will still remain a slave (called it a modern one if you like) slave is slave. It's high time we woke up from our slumbers and be proud of Yorùbá language for it not to go into extinction.
ÌJÀGBARA (REVOLUTION)
Àìfetémete àìfèròmérò,
Ló mú ọmọ bàbá mẹ́fà kú sóko ẹgbàá,
Àìfetémete àìfèròmérò,
Ló mú baba sẹrú, sọ ìyá di ìwọ̀fà,
Tún mú ọmọ náà dọmọ ẹrú tó ń singbà,
Huuuuuuuuuun!
Ọ̀rọ̀ Nàìjíríà yìí níbi tóde gba ete bẹ́ẹ̀ ló gbèrò,
Bí bẹ́ẹ́kọ̀ gbogbo wa lá ó sẹrú,
Ẹrú táwọn baba wa ṣe kù,
làwa tí ìsẹ̀yín tún singbà ẹ̀,
Bá ó bá múra, àfàìmọ káwọn
Èwe ọ̀la wa tún ma sẹrú,
Ọmọọmọ àwọn tí bàbá wa sìn lọ́jósí.
Bá o bá fèteméte, tá o fèròmérò,
Taà ó bá pé èké lékèé,
Taa ó pọ̀dàlẹ̀ lólè,
Ká pọ̀yàmọ́yà tún fí han Ọyà,
Ọyà ò ní mọ̀ pé Ọdẹ ń pọ̀yà.
Baà ó bá yọpin ojú fihan ojú
Kò ní mọ̀ pé ẹ̀gbin lòhun ṣe,
Ba ò bá fẹnìkan jófin nínú àwọn adarí wa,
Ta ò kọ ìyànjẹ látọ̀dọ̀ olórí kan,
Ká jágbe mọ àwọn aṣááju wa lọ́nà tó lápẹrẹ
Wọn ò ní mọ̀ràn-lóràn,
Ayé wa ò ní tẹ̀síwájú,
Ìdàgbàsókè ò ní bá ìlú wa,
Ọ̀rọ̀ ajé wa kò ní gbérù si,
Ọ̀rọ̀ wa kò ní yatọ somi adagun,
Bẹ́ẹ̀ là ó ni kúrò lóko ẹrú yìí bọ̀rọ̀.
Àfi ka fa ìlù bámúbámú ni mo yó wọn ya,
Ká fọ kòkò àìbíkítà wọ́n mọ́lẹ̀,
Ká sun aṣọ alalànlalá wọn níná,
Làwọn ará ibí á tó mọ̀ pé,
Àìda làwọn ńṣe,
Ó dìgbà táa bá yọ ọ̀gá isẹ́ tí ò mọṣ́ẹ́ níṣẹ́,
Táa rọ ìjòyè tí ò pójú òsùnwọ̀n lóyè,
Gbadé lórí Ọba tó ń ṣe kébekèbe,
Da sèríyà fún Dànsákì tó ń jayé fàmílétè ń tutọ́,
Da gbogbo olórí tó ń hùwà táa ni yóó múmi sẹ́wọ̀n,
Lé gbogbo mọ̀lẹ́bí wọn kúrò nílùú,
Sọ sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ sẹ́sẹ̀ àtọwọ́ àwọn ọrẹ wọ́n,
Kán tó mọ pẹ ọ̀rọ̀ ìlú kì í ṣe awéwàá,
Ọ̀rọ̀ orílẹ̀èdè kì í sọ̀rọ̀ àwàdà,
Pé àńfààní lásán làwọn ni,
Ẹ̀tọ́ gbogbo ìlú lówà lọ́wọ́ àwọn.
Ṣùgbọ́n tí gbogbo wa ba dákẹ́
Táa ń pòwe aìdákẹ́ á sìwí,
Aìwósùn ká jẹ̀bi,
Aìgbé ilé ẹni ká fọrùn rọ́,
Táa ò gbé ìgbésẹ̀ ká tó ké pé Olúwa
Àfàìmọ kí wọn máa jẹ ẹ̀tọ́ wá mọ ti wọ́n,
Kí wọ́n ma lò wá mọ́gbà,
Kán ma ta ọjọ́ ọlà àwọn ọmọ wa,
To rí náà àsìkò tó fún wa láti jìjà gbára,
Ká parapọ̀ sọ̀kan kọ ẹ̀gbin,
Lọ́wọ́ àwọn eléré orí ìtàgé tán ńpe ra lólórí,
Àtàwọn oníjẹ gbèse ò kàn mi,
Tán ńpe ará wọn ládarí.
Ẹ jẹ ọmọ ẹrú wa yọdà tì wọn,
Kọ́mọ ìwọ̀fà wa yọ kùmọ̀ yọ kóndó tọ̀ wọ́n lọ,
Ká má jẹ ọmọ olówó wọ́n rímú mi,
Kọmọ ọlọ́rọ̀ wọn ò ráyè nara,
Ìgbà náà ni wọn ó mọ̀ pé,
Kò sí bọ́bọ wọn ṣe sọrí
Tínàkí wa ò ṣe,
Ìgbà náà ni ìwà ọ̀jẹ̀lú wọn ò dẹ́kun,
Tí ayé ó lè ri gbẹdẹmukẹ fún gbogbo wa
Àsìkò tó láti jìjàgbara.
©️Mustapha Sherif
08147675392
J.🅾.R.🅰️
Àrànmọ: ni isodiara-eni to n wáyé láàrin iro méjì nigba ti oro kan ba lo agbára lórí ìró kejì lati sọ o fi ara rẹ. Ìró ti i lo agbára ni a bi pè ni ÌRÓ AFARANMỌ nígbà tí ìró ti a ló agbára le lórí jẹ ÌRÓ AGBÀRÀNMỌ.
Ọmọ aráyé ńpàtẹ́wọ́ fún yànmùyánmú, inú ẹ̀ ńdùn; kò mọ̀ pé òun ńfi ikú ṣeré ni. /
Mosquito rejoices when people clap for it, not realising that it is toying with death.
[Be perceptive: naivety can prove costly; not all doors open to great rooms.]
ORÚKỌ ÀMÚNTỌ̀RUNWA
Pataki ni orúkọ sísọ àti jíjẹ jẹ́ nílẹ̀ Yorùbá, ìdí niyìí ti Yorùbá ṣe karamaski orúkọ tí wọn yoo sọ ọmọ won torí wọn gbà pé orúkọ ọmọ ní ìjánú ọmọ. Oríṣìíríṣìí orúkọ lówá nílẹ̀ bi orúkọ àbísọ, orúkọ ìdílé, oríkì, orúk ìnagije, orúkọ àmútọ̀runwá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n orúkọ àmútọ̀runwá yàtọ̀ gédégédé si ìyókù nítorí wọn kì í sábà fún ọmọ lórúko yìí àyàfi kó jẹ́ pe Ìṣẹ̀lẹ̀ kán ṣẹlẹ̀ yálà ká tó lóyún ọmọ náà, nínú oyún tàbí ìgbà ti wọn máa bí. Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sábà máa ñ jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì. Ìdí nìyìí tí wọn fí máa ba fún àwọn ọmọ wọ̀nyìí lórúko náà tórí Yorùbá gbà pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ tí mu orúkọ wá látọ̀run, orúkọ yìí naa ni wọ́n máa ñ tẹ̀ mọ ọmọ lára kódà bó bá jẹ́ pé wọn fún ní àwọn orúkọ miran.
Ohùn kan tó tún mú orúkọ àmútọ̀runwá yàtọ̀ nipé, àwọn orúkọ náà ni oríkì ti wọn lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí oríkì ìdílé wọn. Síwáju si ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ yìí ni wọ́n máa ñ ṣe ètùtù fún nígbà tan bá dáyé torí wọn gba pé àkàndá ni wọ́n.
Díẹ̀ nínú orúkọ àmúntọ̀runwa àti ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìṣẹ̀ṣe tó yí wọn ká ní ìwọ̀nyí:
1.Táyé: ni àkọ́kọ́ ọmọ nínú Ìbejì
2. Kẹ́hìndé: ni èkejì ọmọ nínú Ìbejì
3. Ẹ̀ta Òkò: ọmọ kẹta àwọn Ìbejì
4. Ìdòwú: ọmọ to a bi tèlé àwọn Ìbejì lobìnrin
5. Àlàbá: ọmọ tí a bi tèlé Ìdòwú
6. Ìdògbé: ọmọ tí abi tèlé Àlàbá
7. Ìdòhá: ọmọ tí a bí tèlé ìdògbé
8 Aina: ọmọbìnrin ti a bi tó gbe ibi kórùn wáyé
9. Ojo: ọmọkùnrin ti a bi tó gbe ibi kọ́rùn wáyé
10. Ìgè: ọmọ tó mú ẹsẹ̀ wáyé dípò orí
11. Ìlọ̀rí: ọmọ tí ìyá rẹ̀ kò ṣe nńkan oṣù tí a fi lóyún rẹ
12. Olúgbódi: ọmọ tó ní ìka ẹsẹ̀ mẹ́fà
13. Òní: ọmọ tó máa ń ké lọ́sàn-án àti lóru nígbà tí a bi
14. Ọ̀la: ọmọ tí a bí tèlé Òní
15. Abíára: ọmọ tí oyún rẹ ko ti i hàn tí bàbá rẹ̀ fi kú
16. Àjàyí: ọmọ tó dójú bolẹ̀ nígbà tí a bi
17. Tàlàbí: ni ọmọ tí a bi tó ekú bo orí àti ara rẹ
18: Ọ̀kẹ́: ọmọ tí a bi tówà nínú àpò
19: Dàda: ọmọ tí a bi tó irun orí rẹ̀ ta kókó
20. Èrinlé: ọmọ ti a bi ti o wé okùn ibi rẹ mọ́ ọwọ́ àbí ẹsẹ̀ wáyé
21. Igisanrín: ọmọ tí ìwọ́ inú rẹ̀ lọ́ wẹ́rẹ́kẹ́ wẹ́rẹ́kẹ́ bí okun ẹ̀ran
22. Amúsàn-án: ọmọkùnrin tí a bí pẹ̀lú isan eégún lọ́wọ́ rẹ̀
23. Ato: ọmọbìnrin ti a bi pẹ̀lú isan eégún lọ́wọ́ rẹ
24. Àṣà: ọmọ tí wọn bi tó su owó méjèèjì pọ.
25. Awẹ́: ọmọ tó kéré pupọ nígbà tí a bi
26. Ọmọpé: ọmọ tí oyún rẹ ju osù mẹ́sàn-án lọ kí wọn tó bi
27. Jọọ̀jọọ̀: ọmọ tí ìyá rẹ̀ kú bó ṣe bi i tan.
Fún ìbéèrè àti àlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́, ẹ pè sórí aago tàbí fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ lórí 08147675392
Owe ni a gbe yewo ninu idani lekoo yii
Hon. Nasir Ibraheem thanks for believing and supporting us @ Kíláàsì Yorùbá.
Warafanahu Monkana Aaliyah
Òwe ni àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó súyọ láti inú àṣà, ı̀ṣe, iṣẹ́, ẹ̀sìn, ìhùwàsí àwọn bàbá wa.
A tún le sọ pé òwe ni ọ̀rọ̀ àjogúnbá ti a gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá wá èyí tí àwọn náà gbà láti ẹnu àwọn bàbá wọn, èyí tí won ń lò láti wa ojútùú sọ́rọ̀ tó bá ta kókó.
Wọn a tún maa sọ pé òwe lẹ́sin ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ lẹsin òwe, bọ̀rọ̀ bá sọnù, òwe la fi ń wa.
Nile Yorùbá ọmọdé kì í pòwe níwájú àgbàlàgbà torí Yorùbá gbà pé ẹnu agbà lobì ń gbó sí, fun idi èyí tí ọmọdé bá fẹ́ pòwe níwájú àgbàlagbà, o ní láti gbàsẹ nípa sisọ gbólóhùn yìí “Ẹ̀yin agbà náà ló wí pé tàbí ẹ̀yin agbà lẹ máa n pa a lówe pe” nígbà míràn tọmọdé ba pòwe laigbasẹ, o ní láti sọ pé “tótó sebí òwe nígbẹ̀yìn”. Yorùbá gbà pé bi ọmọdé ò bá gbàsẹ kó tó pòwe, o lè ma rí òmíràn pa àti pé, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní ẹ̀kọ́ tó.
Oríṣun owe
Gẹ́gẹ́ bi a ti sọ saájú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìì kò jábọ́ lásán ṣùgbọ́n o ní idi kan tabi Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó bi fún idi èyí awon idi wọ̀nyìí là ń pè ni oríṣun owe, lara won ni
1. Ìtándòwe: ni àwọn òwe tó jẹ jáde lati ara ìtàn yálà gídi, ìtàn ìṣẹ̀nbáyé, ìtàn ààlọ́ atbbl. Bí àpẹẹrẹ
a. Ẹni ti o ṣe bi aláàárù lóyìngbò kò lè sebí adégbọrọ̀ lọ́jà ọba
b. Bó ó layà o sèkà, bó ó ránti ikú Gaa kó o ṣòtítọ́ọ́ọ́
d.
2. Àṣádòwe: èyí lè jẹ àṣà ìgbéyàwó, ìsọmọlórúkọ, òkú, oyè jíjẹ atbbl bi àpẹẹrẹ
I. Ìgbéyàwó: Ọbẹ ti báálé ilé kì í jẹ, ìyálé ilé kì í ṣe
b. Ẹni tí a ń gbéyàwó bọ̀wá bá kì í garùn ni ìgànà
d. Àti gbéyàwó ò tẹ́jọ́, owó ọbẹ̀ ló sòro
II. Ìsọmọlórúkọ: orúkọ táa o sọmọ ẹni, inú ẹni ló ńgbé
b. Orúkọ ọmọ ní ìjánú ọmọ
d. Kọ́mọ máa ba daran laṣẹ̀ ń sọ ọ lórúko
III Òkú: bi a ba pé òkú ni pópó Alàayè ni mo dáhùn
b. Ọ̀run ni kan lo mo eni ti yoo la
Oyè jíjẹ: orí tí yoo dádé inú agoro ide ni tí n wa
Baa bá joyè Àwòdì, o ye ká lè da adìẹ gbé
3. Ẹ̀síndowe: awon òwe tó súyọ láti ibi ẹ̀sìn bi àpẹẹrẹ.
a. Ati kékeré ni imọlẹ tí ń Kọ́mọ ẹ lẹ́sìn
Ọ̀kan ẹni nigbagbọ ẹni
4. Òwe tó jẹ jáde láti ibi Ìsesí yálà Ìsesí ẹranko, tàbí téèyàn bi àpẹẹrẹ
a. A fọwọ́ foná kì í mọ́wọ́ dúró
b. Ojú lalákàn ń fi sori
d. Eyin ẹ̀yin lọ́mọ adìẹ ń tọ ìyá ẹ
Ìwúlò Òwe
1. A n fòwe se ìkìlọ̀. Bi àpẹẹrẹ, ẹsẹ̀ gìrì nílé anjọfẹ, anjọfẹ kú, à ò rẹnikan
Agbojulogun fara fósì ta
2. À ń fòwe gbàmọ̀ràn. Bi àpẹẹrẹ: bi a bá mọ tijò ká maa kiesi ẹkunle
B. Bonii t**i ọ̀la le maa ri bee lómú Babaláwo dífá ọrọọrún
3. À ń fòwe ṣe ìbáwí. Àpẹẹrẹ: Afasẹ gbejo ń tan ara rẹ jẹ
B. Aifini peni, aifeeyan peeyan lo n mu ara oko san ibante wọ̀lú
4. À ń fòwe se ìsírí. Àpẹẹrẹ: pípẹ́ ni yoo pẹ́, akálòlò yóó pé baba
B. Ajá tó peku lónìí lé pa odù ọyà Kọ́lá
5. Owe maa n di àròyé ku
6. O máa ń jẹ a gbọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá
Igba o lo bi orere aye o lo bi opa ibon
A ki gbogbo wa kaabo si ìkànì yii, níbi tí a o ti maa kọ ara wa nìpa èdè, àṣà, ı̀ṣe, iṣẹ́, ìhùwàsí àti ẹ̀sìn Yorùbá,