The Living WATER - C.A.C Daily Devotional Guide
A daily devotional guide by Christ Apostolic Church for impacting lives.
*CHRIST APOSTOLIC CHURCH*
*THE LIVING WATER DAILY DEVOTIONAL GUIDE*
*DATE: Monday, September 2, 2024*
*(Organ Donation Week & Coconut Day)*
*TOPIC: HE SACRIFICES ALL*
*MEMORISE:*
And when they crucified Him, they divided His garments, casting lots for them to determine what every man should take *(Mark 15:24).*
*READ: Mark 15:21-32*
21. Then they compelled a certain man, Simon a Cyrenian, the father of Alexander and Rufus, as he was coming out of the country and passing by, to bear His cross.
22. And they brought Him to the place Golgotha, which is translated, Place of a Skull.
23. Then they gave Him wine mingled with myrrh to drink, but He did not take it.
24. And when they crucified Him, they divided His garments, casting lots for them to determine what every man should take.
25. Now it was the third hour, and they crucified Him.
26. And the inscription of His accusation was written above:
27. With Him they also crucified two robbers, one on His right and the other on His left.
28. So the Scripture was fulfilled which says, “And He was numbered with the transgressors.”
29. And those who passed by blasphemed Him, wagging their heads and saying, “Aha! You who destroy the temple and build it in three days,
30. save Yourself, and come down from the cross!”
31. Likewise the chief priests also, mocking among themselves with the scribes, said, “He saved others; Himself He cannot save.
32. Let the Christ, the King of Israel, descend now from the cross, that we may see and believe.” Even those who were crucified with Him reviled Him.
*EXPOSITION*
As today commemorates Organ Donation Week and Coconut Day, it is good to know that Jesus did not just donate an organ in His body, but He gave His entirety for the salvation of mankind. The fulfilment of the prophecy of Christ's birth, death and resurrection as the Saviour of humanity is truly remarkable. Despite being entirely sinless, Jesus willingly embraced His role as the sacrificial Lamb (Isa. 53:3-10). Certainly, Jesus Christ epitomises the concept of sacrifice, temporarily setting aside the splendours of heaven to fulfil His divine mission on Earth. Despite sharing equal status with God, He showed profound humility by not claiming the lofty privileges linked to that status. When the time was right, Jesus willingly relinquished the benefits of His divinity and took on the role of a servant, fully immersing Himself in the human experience. He opted to live a life characterised by selflessness and obedience, leading to His atoning death, the agonising crucifixion. Despite having other potential paths to fulfil His divine destiny, Jesus intentionally chose the challenging journey of Calvary. He could have opted for a quicker and less painful means of death rather than enduring the crucifixion at the hands of His very creatures. Even in moments when the weight of the impending sacrifice could have led Him to contemplate giving up, He remained resolute in adhering to the Father's will.
Reflect on the incredible sacrifice of Christ and the blessings from this. Imagine the transformative, impact if we fully embrace the redemption secured by Christ on our behalf.
*PRAYER POINTS*
1. Lord Jesus, thank You for Your sacrificial life to save me.
2. Lord, let your blood set me free from all chains and shackles.
3. Lord, fill the hearts of ministers of the gospel at all levels with Your attitude of sacrifice, to help us do Your work with the right attitude.
*SUGGESTED HYMN FOR TODAY: CAC GHB: 292*
1. Redemption! Oh, wonderful story
Glad message for you and for me
That Jesus has purchased our pardon,
And paid all the debt on the tree.
*Chorus:*
Believe it, O sinner, believe it,
Receive the glad message-'tis true;
Trust now in the crucified Saviour
Salvation he offers to you.
2. From death unto life He hath brought us
And made us by grace Sons of God;
A fountain is opened for sinners;
Oh, wash and be cleans'd in the blood.
3. No longer shall sin have dominion,
Though present to tempt and annoy;
For Christ , in His blessed redemption,
The power of sin shall destroy.
4. Accept now God's offer of mercy;
To Jesus, oh, hasten today;
For He will received him that cometh,
And never will turn him away.
Amen.
*EXTRA READING FOR TODAY: Ezekiel 7, 8, 9*
*AUTHOR: CAC Worldwide*
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2024)
Òjọ
AJE (Monday) SEPTEMBER 2ND, 2024.
ÀKÒRÍ:
O FI GBOGBO RẸ RUBỌ
AKỌSORI:
Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú (Marku 15:24).
KA:
Marku 15:21-32
[21]. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu.
[22]. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari.
[23]. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a.
[24]. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú.
[25]. Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu.
[26]. A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU.
[27]. Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀.
[28]. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin.
[29]. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta,
[30]. Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá.
[31]. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀.
[32]. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.
ITUPALẸ:
Gẹgẹ bi oni ṣe jẹ ọjọ Iṣeranti Ọsẹ Ijọwọ Ẹya Ara Inu (Kìndinrín) ati ọjọ Àgbọn Lagbaye, o dara lati mọ pe Jesu ò kan jọwọ ẹya ara inu Rẹ ( Kìndinrín) nikan ni agọ ara Rẹ, bikoṣe pe O yọnda gbogbo ara Rẹ fun igbala ẹda eniyan. Imuṣẹ asọtẹlẹ nipa ibi Kristi, iku ati ajinde Rẹ, gẹgẹ bi Olugbala iran eniyan jẹ mani-gbagbe nitootọ. Pẹlu pe O jẹ alailẹṣẹ ni gbogbo ọjọ aye Rẹ, jesu fi tọkantọkan gba ipa Rẹ gẹgẹ bi Ọdọ-aguntan irubọ ( Isa.53:3-10 ). Dajudaju, Jesu Kristi ṣe apẹẹrẹ oye ti irubọ, ti O fi ibi itura ati ayọ silẹ lọrun fun igba diẹ lati wa mu ilepa/iṣẹ Rẹ ṣẹ lori ilẹ aye. Pẹlu pe O dọgba pẹlu Ọlọrun, O ṣafihan irẹlẹ to jinlẹ nipa aibeere fun awọn anfaani to ga to rọ mọ ipo nla naa. Nigba ti akoko tó, Jesu finufindo yọnda awọn anfaani ti jijẹ ẹda Atọrunwa Rẹ O si mu ipa/awọ iranṣẹ, O ti ara Rẹ bọ inu iriri iran eniyan lẹkunrẹrẹ. O gba lati gbe igbe aye ti aimọ-tara-ẹni-nikan ati igbọran ni ṣe abuda rẹ, eyi ti o yọrisi iku etutu Rẹ, ikan mọ-agbelebu onirora Rẹ. Pẹlu bi O ti ni awọn ipa ọna miran to lagbara lati mu ayanmọ atọrunwa Rẹ ṣẹ, jesu mọ-ọn-mọ yan irin-ajo ipenija lọ si Kalfari. Oun iba ti yàn ọna to ya to si rọrun lati ku dipo fifarada ikanmagbelebu lati ọwọ awọn ẹda ọwọ Rẹ gan-an. Koda ni akoko ti iwuwo irubọ to n rọdẹdẹ iba mu ki O ronu jijáwọ́, O duro lori ipinnu Rẹ ni ṣiṣe ifẹ ọkan Baba.
Ronu jinlẹ lori irubọ agbayanu Kristi ati awọn Ibukun lati inu eyi. Wo ipa ti iyipada naa yoo mu wa, bi a ba gba irapada ti Kristi ṣe fun wa lẹkunrẹrẹ.
Awọn koko Adura
1. Jesu Oluwa, O ṣeun fun igbe aye irubọ Rẹ lati gba mi la.
2. Oluwa, jẹ ki ẹjẹ Rẹ sọ mi di ominira kuro ninu gbogbo ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹwọn.
3. Oluwa, kun inu ọkan awọn iranṣẹ ihinrere ni gbogbo ipele pẹlu iwa irubọ Rẹ, lati ran wa lọwọ lati ṣe iṣẹ Rẹ pẹlu iwa títọ́.
Orin Ti A Dabaa: CAC: 292
ỌỌDUNRUN O DIN MẸJỌ
Nitori irapada ọkan wọn iyebiye ni.
OD. 49:8.
1. Irapada! itan iyanu,
Ihin ayo fun gbogbo wa,
Jesu ti ra 'dariji fun wa,
O san 'gbese na lor'igi.
A! elese gba ihin na gbo,
Jo gba ihin oto na gbo,
Gbeke re le Olugbala re
T'O mu igbala fun o wa.
2. Omu wa t'inu'ku bo si'ye,
O si so wa d'om'Olorun;
Orisun kan si fun elese
We nin' eje na ko si mo
3. Ese ki y'o le joba wa mo
B'o ti wu ko dan wa wo to,
Nitori Kristi fi 'rapada
Pa 'gbara ese run fun wa.
4. Gba anu t'Olorun fi lo o.
Sa wa s'odo Jesu loni
'Tori y'o gb'eni t'o ba t'o wa
Ki yi o si da pada lae
Amin.
Afikun Ibi Kika Fun Oni:
Esikiẹli 7, 8, ,9
CHRIST APOSTOLIC CHURCH
THE LIVING WATER (January-December, 2024)
DAILY DEVOTIONAL GUIDE
DATE
Sunday, September 1, 2024
(World Letter Writing Day)
TOPIC:
YOU ARE CHRIST'S EPISTLE
MEMORISE
Clearly you are an epistle of Christ, ministered by us, written not with ink but by the Spirit of the living God, not on tablets of stone but on tablets of flesh, that is, of the heart. (2 Corinthians 3:3)
READ
Corinthians 3:1-3
[1]. Do we begin again to commend ourselves? Or do we need, as some others, epistles of commendation to you or letters of commendation from you?
[2]. You are our epistle written in our hearts, known and read by all men;
[3]. clearly you are an epistle of Christ, ministered by us, written not with ink but by the Spirit of the living God, not on tablets of stone but on tablets of flesh, that is, of the heart.
EXPOSITION
The word "epistle" comes from Greek, epistolé ("letter," "message," or "dispatch"), even as today marks World Letter Writing Day. In Hebrew, it is iggerah, also meaning "letter" and mainly used for missives (communiqués)-long, official, formal letters, usually from someone in an important capacity. In the NT, epistles were initially written as letters to the early Christians. Paul emphasised to the Corinthian brethren that the Lord God chose them to be a message for the world. God has chosen to use Christians as His letter to the world, conveyed in their actions and attitudes. Do you believe this applies to you today? Can the world perceive God's true nature and Power through your words and actions? Paul's letter to Timothy emphasised his role as a representative of Christ, commanding Timothy to follow his teachings and leading by example (2 Tim. 3:10-15). This underscores the idea that Christianity is more than mere rituals, but a way of life centred around Christ. We are compared to a letter written by preachers, widely recognised and read by all, and most importantly, a letter from Christ that revealed God's nature to the world (2 Cor. 3:2; 5:18-20). Therefore, it was crucial for Timothy to accurately portray God through his actions. What are you doing with life. What signal are you sending to the world around. Consider these things.
PRAYER POINTS
1. Lord, help me to always remember that I am to represent You in this world.
2. Here am I, O Lord God, use me entirely for Your glory alone.
3. Pray for our children in schools and on campuses to always remember that they are representing God wherever they are.
SUGGESTED HYMN FOR TODAY:
CAC GHB: 793
1. Shining for Jesus everywhere I go
Shining for Jesus in this world of woe
Shining for Jesus, more
Like Him I grow
Shining all the time for Jesus.
Shining all the time
Shining all the time
Shining for Jesus,
Beams of love divine
Glorifying Him every day and hour
Shining all the time for Jesus.
2. Shining for Jesus when the way is bright
Shining for Jesus in the darkest night
Shining for Jesus, making burdens light
Shining all the time for Jesus.
3. Shining for Jesus in a world of sin
Shining for Jesus bringing lost ones in
Shining for Jesus, glorifying him
Shining all the time for Jesus.
4. Shining for Jesus when He gives me grace
Shining for Jesus, while I run the race
Shining for Jesus, till I see His face
Shining all the time for Jesus.
Amen.
EXTRA READING FOR TODAY:
Ezekiel 4, 5, 6
AUTHOR
CAC Worldwide
Remain blessed
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2024)
Òjọ
AIKU (Sunday) SEPTEMBER 1ST, 2024.
ÀKÒRÍ:
EPISTELI KRISTI NI Ọ
AKỌSORI:
Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran (2 Kọrinti 3:3).
KA:
2 Kọrinti 3:1-3
[1]. AWA ha tún bẹ̀rẹ lati mã yìn ara wa bi? tabi awa ha nfẹ iwe iyìn sọdọ nyin, tabi lati ọdọ nyin bi awọn ẹlomiran?
[2]. Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà:
[3]. Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran.
ITUPALẸ:
Ọrọ yii "episteli" wá lati inu ede Giriki " epistole " ("lẹta", " Ọrọ/iṣẹ" tabi lati " ran Jade"), ani gẹgẹ bi oni ṣe n ṣami si Ọjọ Lẹta kikọ Lagbaye. Ni Heberu, o jẹ " iggerah" , ti o tun tumọ si " lẹta/iwe" a si n lo o fun akọsilẹ ọ̀rọ̀ (asọyepọ)---- o maa n gùn, o jẹ onilana, lẹta aigbagbẹfẹ, ti o saaba maa n wa lati ọdọ ẹnikan ti o di ipo pataki mu. Ninu Majẹmu Tuntun, awọn episteli ni a ki kọkọ kọ gẹgẹ bii lẹta si awọn Kristiẹni iṣaaju. Pọọlu tẹnumọ ọn fun awọn ara Kọrinti pé Oluwa Ọlọrun ti yan wọn lati jẹ iwe (iṣẹ) fun aye. Ọlọrun ti yan lati lo awọn Kristiẹni gẹgẹ bi lẹta fun aye, ti wọn n gbe kiri ninu awọn iṣesi ati ihuwasi wọn. Njẹ o gbagbọ pe eyi n ba ọ wi lonii bi? Ṣe aye le gboorun/ri iwa Ọlọrun tootọ ati Agbara Rẹ nipasẹ ọ̀rọ ati iṣe rẹ? Lẹta Pọọlu si Timoteu n tẹnumọ ipa/ojuṣe rẹ gẹgẹ bi aṣoju Kristi, o paṣẹ fun Timoteu lati maa tẹle awọn ẹkọ ati idari rẹ nipa apẹẹrẹ (2 Tim. 3:10-15). Eyi n sọ niti òye pe ẹsin Kristiẹni kọja iṣerubọ lasan, bikoṣe ọna iye to duro lori Kristi. A n fi wa we lẹta ti awọn oniwaasu kọ, ti gbogbo eniyan mọ ti wọn si n ka, ati ni pataki julọ, lẹta lati ọdọ Kristi ti n ṣafihan ẹda/abuda Ọlọrun fun aye (2 Kọr. 3:2; 5:18-20). Nitori naa, o ṣe pataki fun Timotiu lati maa ṣafihan Ọlọrun bi o ti yẹ nipasẹ iṣesi rẹ. Kin ni o n ṣe pẹlu igbe aye rẹ? Iru apẹẹrẹ ẹkọ wo ni o fi n kọ aye to yi ọ ka? Maa ro nnkan wọnyi.
Awọn koko Adura
1. Oluwa, ran mi lọwọ lati maa ranti nigba gbogbo pe mo n ṣoju Rẹ ninu aye yii.
2. Emi ni yii, Oluwa Ọlọrun, lo mi patapata fun Ogo Rẹ nikan.
3. Gbadura fun awọn ọmọ wa ti wọn wa ni awọn ile ẹkọ ati awọn ile ẹkọ giga lati maa ranti nigba gbogbo pé wọn n ṣoju Ọlọrun nibikibi ti wọn ba wa.
Orin Ti A Dabaa: CAC: 793
ẸGBẸRIN O DIN MEJE
Ẹyin ni imọlẹ aye.
Mat.5:14.
1. Mo fe ki nje imole fun Jesu
Nibikibi, ki nfi ewa Re han,
Ki nma dagba n'nu ore-ofe Re,
Ki nje imole Re l'aye.
Ki ntan imole, ki ntan imole,
Ki ntan 'mole, ife atorunwa;
Ki nma f'ogo fun l'osan at'oru,
Ki nma tan 'mole fun Jesu.
2. Mo fe ki nje imole fun Jesu,
Ninu ayo tabi ibanuje;
Ki nje 'ranlowo f'awon t'eru npa,
Ki nje imole Re l'aye.
3. Mo fe ki nje imole fun Jesu,
Imole ninu aye ese yi;
Ki nmu awon ti nsako pada bo,
Ki nma gbe oruko Re ga.
4. Mo fe ki nje imole fun Jesu,
Ki nfi tayotayo sure 'je mi;
Ki ngbekele or'ofe Re nikan
T**i uno fi ri oju Re
Amin.
Afikun Ibi Kika Fun Oni:
Esikiẹli 4, 5, 6
CHRIST APOSTOLIC CHURCH
THE LIVING WATER (January-December, 2024)
DAILY DEVOTIONAL GUIDE
DATE
Saturday, August 31, 2024
TOPIC:
GOD'S WORD NEVER FAILS
MEMORISE
Not a word failed of any good thing which the LORD had spoken to the house of Israel. All came to pass (Joshua 21:45).
READ
Joshua 21: 43-45
[43]. So the Lord gave to Israel all the land of which He had sworn to give to their fathers, and they took possession of it and dwelt in it.
[44]. The Lord gave them rest all around, according to all that He had sworn to their fathers. And not a man of all their enemies stood against them; the Lord delivered all their enemies into their hand.
[45]. Not a word failed of any good thing which the Lord had spoken to the house of Israel. All came to pass.
EXPOSITION
It is of utmost importance that we prioritise and give heed to what God says about us, placing them above the prevailing opinions of society. We have a duty to fulfil the divine plans and purposes that God has ordained for our lives. Our text today shows that God had previously revealed to their forefathers the land that would be their inheritance. However, their journey was not without its challenges, as they encountered numerous obstacles and engaged in battles with various nations before finally reaching the Promised Land. God's promises don't automatically come to realisation; rather, we must remain unwavering and determined in the face of adversity.
When confronted with challenges along our own paths, it is imperative that we understand how to respond appropriately. Firstly, we must be adequately prepared in the Lord to confront and overcome these challenges. Don't shy away from, or underestimate the obstacles that can impede your progress towards your promised land. Stand resolute and fight, relying on God's strength and power in Christ to ultimately achieve victory. Also, always remember and hold fast to God's promises in His Word. This helped Joshua a lot in successfully possessing the land that God had promised their forefathers. It is unfortunate that many of God's promises remain unfulfilled in our lives due to our lack of perseverance. Firmly believe that no Word of God will go unfulfilled.
PRAYER POINTS
1. Lord Jesus, help me to know Your power in this confused World.
2. Grant me the opportunity to rely on Your Word for the fulfilment of Your promises for my life, Oh Lord.
3. Lord Jesus, prove further through, and in Your Church in the land, that Your Word never fails.
SUGGESTED HYMN FOR TODAY:
CAC GHB: 458
1. Lord, Thy word abideth,
And, our footsteps guideth;
Who its truth believeth
Light and joy receiveth.
2. When our foes are near us,
Then Thy word doth cheer us,
Word of consolation
Message of salvation.
3. When the storms are o'er us,
And dark clouds before us,
Then its light directeth.
And our way protecteth.
4. Who can tell the pleasure,
Who recount the treasure,
By Thy word imparted
To the simple-hearted?
5. Word of mercy, giving
Succour to the living;
Word of life, supplying
Comfort to the dying!
6. O that we, discerning
Its most holy learning,
Lord, may love and fear Thee,
Evermore be near Thee!
Amen.
EXTRA READING FOR TODAY:
Ezekiel 2, 3
AUTHOR
CAC Worldwide
Remain blessed
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2024)
Òjọ
ABAMẸTA (Saturday) AUGUST 31ST, 2024.
ÀKÒRÍ:
ỌRỌ ỌLỌRUN KII YẸ
AKỌSORI:
Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ (Joṣua 21:45 )
KA:
Joṣua 21:43-45
[43]. OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀.
[44]. OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ.
[45]. Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ.
ITUPALẸ:
O jẹ ohun ti o pọndandan fun wa lati fi ohun ti Ọlọrun sọ nipa wa ṣaaju ki a si gbọran si i, ki a si gbe wọn leke awọn erongba to gbodekan ni awujọ. A ni ojuṣe lati mu awọn eto ati erongba atọrunwa ti Ọlọrun ti la kalẹ fun aye wa ṣẹ. Ibi kika wa oni fihan pe Ọlọrun ti fi han awọn baba nla wọn latẹyinwa pe ilẹ naa yoo jẹ ogun ini wọn. Sibẹ irin-ajo wọn ko ṣalai ni ipenija, nitori wọn ni iriri oniruuru idena, wọn si ba ọpọlọpọ orilẹ-ede jagun ki wọn to de Ilẹ Ileri nikẹyin. Awọn ileri Ọlọrun kii ṣa dede wa si imuṣẹ; nitori naa a gbọdọ duro laiyẹsẹ ki a si ṣe ipinnu nigba ti a wa n koju iṣoro.
Nigba ti a ba n koju awọn ipenija ni oju ọna wa, o pọndandan ki a ni oye nipa bi a o ti gbe igbesẹ ti o tọ. Lakọkọ, a gbọdọ murasilẹ daradara ninu Oluwa lati koju ati bori awọn ipenija wọnyii. Maṣe sá fun wọn tabi fojurena awọn idiwọ to le dena itẹsiwaju rẹ si ilẹ ileri rẹ. Duroṣinṣin ki o si jà, bi o ti n sinmile ipá ati agbara Ọlọrun ninu Kristi lati mu iṣẹgun naa waye nikẹyin. Bakan naa maa ranti, ki o si di awọn ileri Ọlọrun mú ṣinṣin ninu Ọrọ Rẹ. Eyi ran Joṣua lọwọ pupọ lati ṣaṣeyọri ninu gbigba ilẹ naa ti Ọlọrun ti ṣeleri fun awọn baba-nla wọn. O jẹ ohun ti o bani ninu jẹ pe ọpọ awọn ileri Ọlọrun ni ko wa si imuṣẹ ninu aye wa nitori aini ifarada wa. Ni igbagbọ to fẹsẹmulẹ pe ko si Ọrọ Ọlọrun ti yoo lọ lai wá si imuṣẹ.
Awọn koko Adura
1. Jesu Oluwa, ran mi lọwọ lati mọ agbara Rẹ ninu aye rudurudu yii.
2. Fun mi ni anfaani lati sinmile Ọrọ Rẹ fun imuṣẹ awọn ileri Rẹ fun aye mi, Oluwa.
3. Jesu Oluwa, fihan siwaju sii nipasẹ ati ninu Ijọ Rẹ laye pe Ọrọ Rẹ kii yẹ̀.
Orin Ti A Dabaa: CAC: 458
ỌTALENIRINWO O DIN MEJI
Ọrọ Rẹ ni fitila fun ẹsẹ mi ati imọlẹ si ipa ọna mi.
O.D. 119:105.
1. Jesu ọrọ Rẹ ye,
O si nto 'sise wa,
Eni t'o ba gba gbo,
Y'o l'ayo oun 'mole.
2. Nigb' ota sunmo wa,
Oro Re l'odi wa;
Oro itunu ni,
Iko igbala ni.
3. B'igbi at'okunkun
Tile bo wa mole;
'Mole Re yo to wa,
Y'o si dabobo wa.
4. Tani le so ayo,
To le ka isura
Ti oro Re nfi fun
Okan onirele
5. Oro anu o nfi
'Lera fun alaye;
Oro iye o nfi
Itunu feni nku.
6. Awa iba le mo
Eko ti O nkoni;
Ki a ba le fe O.
K'a si le sunmo O.
Amin.
Afikun Ibi Kika Fun Oni:
Esikiẹli 2, 3
CHRIST APOSTOLIC CHURCH
THE LIVING WATER (January-December, 2024)
DAILY DEVOTIONAL GUIDE
DATE
Friday, August 30, 2024
(International Day of the Victims of Enforced Disappearance)
TOPIC:
MONEY KNOWS NO STATUS; EARN IT LEGITIMATELY
MEMORISE
A feast is made for laughter, and wine makes merry, but money answers all things (Ecclesiastes 10:19).
READ
Ecclesiastes. 9:10-13;
11:1-6
Ecclesiastes. 9:10-13
[10]. Whatever your hand finds to do, do it with your might; for there is no work or device or knowledge or wisdom in the grave where you are going.
[11]. I returned and saw under the sun that—
the race is not to the swift, nor the battle to the strong, nor bread to the wise, nor riches to men of understanding, nor favor to men of skill; but time and chance happen to them all.
[12]. For man also does not know his time: like fish taken in a cruel net, like birds caught in a snare, so the sons of men are snared in an evil time, when it falls suddenly upon them.
[13]. This wisdom I have also seen under the sun, and it seemed great to me:
Ecclesiastes. 11:1-6
[1]. Cast your bread upon the waters, for you will find it after many days.
[2]. Give a serving to seven, and also to eight,
for you do not know what evil will be on the earth.
[3]. If the clouds are full of rain, they empty themselves upon the earth; and if a tree falls to the south or the north, in the place where the tree falls, there it shall lie.
[4]. He who observes the wind will not sow, and he who regards the clouds will not reap.
[5]. As you do not know what is the way of the wind, or how the bones grow in the womb of her who is with child, so you do not know the works of God who makes everything.
[6]. In the morning sow your seed, and in the evening do not withhold your hand; for you do not know which will prosper, either this or that,
or whether both alike will be good.
EXPOSITION
Many rich people, both in the past and present, came from humble beginnings. This shows that having a high status doesn't always mean having a prestigious background. This is important to teach ambitious young people. Some young people today are so focused on getting rich that they engage in dangerous activities like drug dealing and violence. However, it is important to understand that success and wealth don't come easily. They require hard work and even divine intervention. Even jobs that are not considered "white- collar" can be very profitable. It is important to work hard and not be idle, as idleness can lead to bad things.
Jobs like farming, animal husbandry and security are important and not looked down upon. In fact, God is often compared to a farmer who takes care of His people. Starting with a simple job like driving or sales can lead to success in entrepreneurship. Getting a higher education can also help improve skills and lead to excellence in various fields. This approach is a practical way to address the widespread problems of unemployment and the temptation to engage in criminal activities and wrongdoings. It is important to note that no government has a perfect solution to the issue of unemployment. However, you have the ability to initiate something small and develop it into your desired successful outcome, as today commemorates National Small Industry Day, National Beach Day, International Whale Shark Day and International Day of the Victims of Enforced Disappearance. This is the true story of numerous successful persons globally. May you achieve greatness, in the name of Jesus Christ. Amen.
PRAYER POINTS
1. Thank our great God from Whom comes provision and promotion.
2. Pray to God to make a way for you where there is none, and help you to make good money onto His glory.
3. Repent of every wasted opportunity. Rebuke every spirit of laziness and redundancy in your life in Jesus' name.
SUGGESTED HYMN FOR TODAY:
CAC GHB: Var 14
1. As I journey thro' the land singing as I go
Pointing souls to calvary-to the crimson flow,
Many arrows pierce my soul from without, within;
But my Lord leads me on, through him I must win
Oh, I want to see Him, look upon His face
There to sing for ever of His saving grace
On the streets of glory let me lift my voice;
Cares all past, home at last, ever to rejoice.
2. When in service for my Lord, dark may be the night
But I'll cling more close to him,He will give me light
Satan's snares may vex my soul, turn My thought aside;
But my Lord goes ahead, leads what'er betide
3. When in valleys low I look towards the mountain height,
And behold my Saviour there, leading in the fight.
With a tender hand outreached
Towards the valley low,
Guiding me, I can see, as I onward go.
4. When before me billows rise from the mighty deep,
Then my Lord directs my barque,
He doth safely keep,
And He leads me gently on through
This world below,
He's a real Friend to me, oh, I Love Him so.
Amen.
EXTRA READING FOR TODAY:
Lamentation 4, 5, Ezekiel 1,
AUTHOR
CAC Worldwide
Remain blessed
ÌJỌ ÀPỌ́SÍTÉLÌ KRISTI
Naijiria àti Oke Okun
OMI IYE NAA, (January- December, 2024)
Òjọ
ẸTI (Friday) AUGUST 30TH, 2024.
ÀKÒRÍ:
OWÓ KO MỌ IPO KANKAN; NI IN NI ỌNA TI O TỌ́
AKỌSORI:
Ẹrín li a nsàse fun, ati ọti-waini ni imu inu alãye dùn: owo si ni idahùn ohun gbogbo (Oniwaasu 10:19).
KA:
Oniwaasu 9:10-13; 11:1-6
Oniwaasu 9: 10-13
[10]. Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.
[11]. Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn.
[12]. Nitoripe enia pẹlu kò mọ̀ ìgba tirẹ̀; bi ẹja ti a mu ninu àwọn buburu, ati bi ẹiyẹ ti a mu ninu okùn; bẹ̃li a ndẹ awọn ọmọ enia ni ìgba buburu, nigbati o ṣubu lù wọn lojiji.
[13]. Ọgbọ́n yi ni mo ri pẹlu labẹ õrùn, o si dabi ẹnipe o tobi fun mi.
Oniwaasu 11:1-6
[1]. FUN onjẹ rẹ si oju omi; nitoriti iwọ o ri i lẹhin ọjọ pupọ.
[2]. Fi ipin fun meje ati fun mẹjọ pẹlu, nitoriti iwọ kò mọ̀ ibi ti yio wà laiye.
[3]. Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe.
[4]. Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ kì yio funrugbin; ati ẹniti o si nwòju awọsanma kì yio ṣe ikore.
[5]. Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo.
[6]. Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna.
ITUPALẸ:
Ọpọ awọn ọlọla, ni igba atijọ ati ni isinsin yii jẹ atápàta dide. Eyi fihan pe wiwa ni ipo giga ko saaba tumọ si pe eniyan wa lati idile ọlọla. Eyi ṣe pataki lati fi kọ́ awọn ọdọ ti wọn ni ipongbẹ ọkan. Awọn ọdọ kan lode oni ni afojusun lati di olowo debi pe wọn yoo maa lọwọ ninu awọn iṣẹ to lewu jọjọ bii gbigbe oogun olóró ati iwa ipá. Ṣugbọn o ṣe pataki lati mọ pe aṣeyọri ati ọrọ̀ ko rọrun lati ni. Wọn gba iṣẹ aṣekara ati idasi atọrunwa paapaa. Koda awọn iṣẹ ti a gba pe wọn kii ṣe iṣẹ ijọba le ni èrè lori pupọpupọ. O ṣe koko lati tẹramọṣẹ ki a ma ṣọlẹ nitori yiya ọlẹ le yọrisi ọpọ ohun buburu.
Awọn iṣẹ bii, iṣẹ àgbẹ̀ dida oko, ohun ọsin, ati iṣe alaabo ṣe pataki a ko si le foju tẹmbẹlu wọn. Koda, a fi Ọlọrun wé agbẹ to n ṣetọju awọn eniyan Rẹ. Bibẹrẹ pẹlu iṣẹ kekere bii iṣẹ awakọ tabi ọja tita le yọrisi didi òwò nla. Nini imọ ẹkọ iwe giga naa tun le mu ki eniyan o ni ọgbọn sii, a si yọrisi aṣeyọri/itayọ ni oniruuru ẹka iṣẹ. Ilana yii jẹ ọna afojuri lati koju awọn iṣoro aisi iṣẹ to gbalégbọ̀nà kan yii ati adanwo lati maa lọwọ ninu awọn iwa ọdaran ati awọn ohun ti o lodi. O ṣe pataki lati mọ pe ko si Ijọba to ni ọna abayọ to dantọ si iṣoro aisi iṣẹ yii. Ṣibẹ, o ni agbara lati ṣagbekalẹ ohun kekere ki o si mu un dagba lati di iru ohun aṣeyọri ti o fẹ, bi oni ti n ṣami si Ọjọ Ile -- Iṣẹ kekere, Ọjọ Akojọpọ Omi to Kun fun Ọpọ Iyanrin, Ọjọ Ẹja Nla " Whale Shark" ati Ayajọ Ọjọ Awọn Eniyan Ti Ààjà Gbé Lọ lagbaye. Bi itan awọn eniyan kan ti wọn ti ṣaṣeyọri lagbaye ti ri ni yii. Iwọ yoo de ibi giga, ni orukọ Jesu. Amin.
Awọn koko Adura
1. Dupẹ lọwọ Ọlọrun nla wa lati ọdọ Ẹni ti ipese ati igbega ti n wá.
2. Gbadura si Ọlọrun pe ki O la ọna fun ọ nibi ti o ti dabii pe kosi ọna ki O si ran ọ lọwọ lati ní owó ni ọna ti o tọ́ fun Ogo Rẹ.
3. Ronupiwada awọn anfaani ti o ti fi ṣofo. Ba gbogbo ẹmi ọlẹ ati aigbe igbesẹ ti o tọ wi ninu aye rẹ.
Orin Ti A Dabaa: CAC: Oniruuru 14
ORIN IKẸRINLA
Nwọn o si ma ri oju Rẹ; orukọ Rẹ yo si ma wa ni iwaju wọn.
Ifi. 22:4
1. Ninu irin ajo mi beni mo nkorin
Mo ntoka si Kalfari s'ibi eje na
Idanwo lode ninu l'ota gbe dide
Jesu l'O nto mi lo isegun daju
A! mo nfe ri Jesu, Ki nma w' oju Re
Ki nma korin t**i, nipa ore Re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo ho, ija tan, mo de ile mi
2. Ninu ise isin mi, b'okunkun ba su
Un o tubo sunmo Jesu y'O tan imole
Esu le gb' ogun ti mi ki nle sa pada
Jesu l'o nto mi lo, ko s'ewu fun mi.
3. Bi mo tile bo sinu afonifoju
Imole itoni Re y'o mole si mi
Y'o na owo Re si mi, y'O gbe mi soke
Uno ma tesiwaju b'O ti nto mi lo.
4. Nigbati igbi aye yi ba nyi lu mi
Mo ni abo t'o daju labe apa Re
Y'O ma f'owo Re to mi t**i de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f'E to
Amin.
Afikun Ibi Kika Fun Oni:
Ẹkun Jeremiah 4, 5, Esikiẹli 1.